Luke 20:20-26

Sísan owó orí fún Kesari

20 aWọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. 21 bWọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”

23Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24“Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?”

Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”

25 cÓ sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

26Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

Copyright information for YorBMYO